Native Bible

Exodus 32:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, Èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.

Exodus 32:33 in English

Exodus 32:33 · Berean Standard Bible

The LORD replied to Moses, “Whoever has sinned against Me, I will blot out of My book.

Context

31Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 32Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.” 33Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, Èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì Èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, Èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” 35Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.