Eksodu 32:31
Exodus 32:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn.
Exodus 32:31 in English
Exodus 32:31 · Berean Standard Bible
So Moses returned to the LORD and said, “Oh, what a great sin these people have committed! They have made gods of gold for themselves.
Context
29Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.” 30Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.” 31Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 32Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.” 33Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, Èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.