Native Bible

Exodus 32:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ènìyàn.

Exodus 32:28 in English

Exodus 32:28 · Berean Standard Bible

The Levites did as Moses commanded, and that day about three thousand of the people fell dead.

Context

26Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká. 27Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wí pé, ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’ ” 28Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ènìyàn. 29Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.” 30Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.