Native Bible

Exodus 32:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin.

Exodus 32:15 in English

Exodus 32:15 · Berean Standard Bible

Then Moses turned and went down the mountain with the two tablets of the Testimony in his hands. They were inscribed on both sides, front and back.

Context

13Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ” 14Nígbà náà ni Olúwa dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́. 15Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin. 16Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà. 17Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.