Native Bible

Exodus 30:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Aaroni yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fìtílà náà ṣe.

Exodus 30:7 in English

Exodus 30:7 · Berean Standard Bible

And Aaron is to burn fragrant incense on it every morning when he tends the lamps.

Context

5Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kasia, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà. 6Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ ìkélé, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé. 7“Aaroni yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fìtílà náà ṣe. 8Aaroni yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ́, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ń bọ̀. 9Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí i rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.