Eksodu 30:21
Exodus 30:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.”
Exodus 30:21 in English
Exodus 30:21 · Berean Standard Bible
Thus they are to wash their hands and feet so that they will not die; this shall be a permanent statute for Aaron and his descendants for the generations to come.”
Context
19Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀. 20Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa, 21wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.” 22Olúwa sọ fún Mose pé, 23“Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kilogiramu mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́ta lé nígba (250) ṣékélì,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.