Eksodu 30:18
Exodus 30:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀.
Exodus 30:18 in English
Exodus 30:18 · Berean Standard Bible
“You are to make a bronze basin with a bronze stand for washing. Set it between the Tent of Meeting and the altar, and put water in it,
Context
16Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ yóò sì fi lélẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú Olúwa, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” 17Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé, 18“Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀. 19Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀. 20Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.