Eksodu 3:10
Exodus 3:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”
Exodus 3:10 in English
Exodus 3:10 · Berean Standard Bible
Therefore, go! I am sending you to Pharaoh to bring My people the Israelites out of Egypt.”*
Context
8Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. 9Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. 10Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.” 11Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?” 12Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé, èmi ni ó rán ọ lọ, nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.