Native Bible

Exodus 3:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run.

Exodus 3:1 in English

Exodus 3:1 · Berean Standard Bible

Meanwhile, Moses was shepherding the flock of his father-in-law Jethro,* the priest of Midian. He led the flock to the far side of the wilderness and came to Horeb,* the mountain of God.

Context

1Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. 2Níbẹ̀ ni angẹli Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run. 3Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.