Eksodu 29:42
Exodus 29:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rọ̀;
Exodus 29:42 in English
Exodus 29:42 · Berean Standard Bible
For the generations to come, this burnt offering shall be made regularly at the entrance to the Tent of Meeting before the LORD, where I will meet you to speak with you.
Context
40Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu. 41Ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa. 42“Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rọ̀; 43níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Israẹli, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́. 44“Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.