Eksodu 29:31
Exodus 29:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan.
Exodus 29:31 in English
Exodus 29:31 · Berean Standard Bible
You are to take the ram of ordination and boil its flesh in a holy place.
Context
29“Aṣọ mímọ́ Aaroni yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́. 30Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní Ibi Mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje. 31“Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan. 32Ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀. 33Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi ṣe ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn. Ṣùgbọ́n àlejò ni kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.