Eksodu 29:3
Exodus 29:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ yóò sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà.
Exodus 29:3 in English
Exodus 29:3 · Berean Standard Bible
put them in a basket, and present them in the basket, along with the bull and the two rams.
Context
1“Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọn lè máa ṣe àlùfáà fún mi. Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù. 2Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí. 3Ìwọ yóò sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà. 4Nígbà náà ni ìwọ yóò mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n. 5Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, àti aṣọ ìgúnwà efodu, àti efodu, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu dì í.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.