Eksodu 28:32
Exodus 28:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.
Exodus 28:32 in English
Exodus 28:32 · Berean Standard Bible
with an opening at its top in the center. Around the opening shall be a woven collar with an opening like that of a garment,* so that it will not tear.
Context
30Bákan náà ìwọ yóò sì mu Urimu àti Tumimu sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Aaroni nígbàkígbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Aaroni yóò sì máa ru ohun ti a ń fi ṣe ìpinnu fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọkàn rẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Olúwa. 31“Ìwọ yóò ṣì ṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù efodu náà ní kìkì aṣọ aláró, 32pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya. 33Ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú ṣaworo wúrà láàrín wọn. 34Àwọn ṣaworo wúrà àti àwọn pomegiranate ni kí ó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.