Native Bible

Exodus 28:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bákan náà ìwọ yóò sì mu Urimu àti Tumimu sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Aaroni nígbàkígbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Aaroni yóò sì máa ru ohun ti a ń fi ṣe ìpinnu fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọkàn rẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Olúwa.

Exodus 28:30 in English

Exodus 28:30 · Berean Standard Bible

And place the Urim and Thummim * in the breastpiece of judgment, so that they will also be over Aaron’s heart whenever he comes before the LORD. Aaron will continually carry the judgment of the sons of Israel over his heart before the LORD.

Context

28Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù efodu pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù efodu náà. 29“Nígbàkígbà tí Aaroni bá wọ Ibi Mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinnu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa. 30Bákan náà ìwọ yóò sì mu Urimu àti Tumimu sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Aaroni nígbàkígbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Aaroni yóò sì máa ru ohun ti a ń fi ṣe ìpinnu fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọkàn rẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Olúwa. 31“Ìwọ yóò ṣì ṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù efodu náà ní kìkì aṣọ aláró, 32pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.