Native Bible

Exodus 26:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é.

Exodus 26:31 in English

Exodus 26:31 · Berean Standard Bible

Make a veil of blue, purple, and scarlet yarn, and finely spun linen, with cherubim skillfully worked into it.

Context

29Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà. 30“Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ́ lórí òkè. 31“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 32Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin. 33Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà Ibi Mímọ́ kúrò ní Ibi Mímọ́ Jùlọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.