Native Bible

Exodus 23:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.

Exodus 23:9 in English

Exodus 23:9 · Berean Standard Bible

Do not oppress a foreign resident, since you yourselves know how it feels to be foreigners; for you were foreigners in the land of Egypt.

Context

7Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre. 8“Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́. 9“Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti. 10“Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.