Eksodu 23:17
Exodus 23:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Olódùmarè.
Exodus 23:17 in English
Exodus 23:17 · Berean Standard Bible
Three times a year all your males are to appear before the Lord GOD.
Context
15“Ṣe àjọ àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Abibu, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo. 16“Ṣe àjọ ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.
“Ṣe àjọ àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó ìre oko rẹ jọ tan. 17“Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Olódùmarè. 18“Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti àkàrà tó ní ìwúkàrà.
“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀. 19“Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ.
“Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.