Eksodu 21:3
Exodus 21:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó bá wá ní òun nìkan, òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ.
Exodus 21:3 in English
Exodus 21:3 · Berean Standard Bible
If he arrived alone, he is to leave alone; if he arrived with a wife, she is to leave with him.
Context
1“Wọ̀nyí ni àwọn òfin tí ìwọ yóò gbé sí iwájú wọn. 2“Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Heberu ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà. 3Bí ó bá wá ní òun nìkan, òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ. 4Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan. 5“Bí ẹrú náà bá sì wí ní gbangba pé, mo fẹ́ràn olúwa mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ, èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmìnira mọ́,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.