Native Bible

Exodus 18:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”

Exodus 18:14 in English

Exodus 18:14 · Berean Standard Bible

When his father-in-law saw all that Moses was doing for the people, he asked, “What is this that you are doing for the people? Why do you sit alone as judge, with all the people standing around you from morning till evening?”

Context

12Jetro, àna Mose, mú ẹbọ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Aaroni àti gbogbo àgbàgbà Israẹli sì wá láti bá àna Mose jẹun ní iwájú Ọlọ́run. 13Ní ọjọ́ kejì, Mose jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mose fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. 14Nígbà tí àna Mose rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń ṣe sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jókòó gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?” 15Mose dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. 16Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrín ẹnìkínní àti ẹnìkejì, èmi a sì máa mú wọn mọ òfin àti ìlànà Ọlọ́run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.