Eksodu 16:2
Exodus 16:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà.
Exodus 16:2 in English
Exodus 16:2 · Berean Standard Bible
And there in the desert they all grumbled against Moses and Aaron.
Context
1Ìjọ àwọn ọmọ Israẹli mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Elimu, wọ́n dé sí ijù Sini tí ó wà láàrín Elimu àti Sinai, ni ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. 2Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà. 3Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.” 4Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.