Eksodu 16:12
Exodus 16:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
Exodus 16:12 in English
Exodus 16:12 · Berean Standard Bible
“I have heard the grumbling of the Israelites. Tell them, ‘At twilight * you will eat meat, and in the morning you will be filled with bread. Then you will know that I am the LORD your God.’”
Context
10Ó sì ṣe bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, wọn si bojú wo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọsánmọ̀. 11Olúwa sọ fún Mose pé, 12“Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ” 13Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká. 14Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsi i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.