Eksodu 15:23
Exodus 15:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò. (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò.)
Exodus 15:23 in English
Exodus 15:23 · Berean Standard Bible
And when they came to Marah,* they could not drink the water there because it was bitter. (That is why it was named Marah.)
Context
21Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé,
“Ẹ kọrin sí Olúwa,
nítorí òun ni ológo jùlọ.
Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún,
ni òun bi ṣubú sínú Òkun.” 22Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun Pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi. 23Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò. (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò.) 24Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?” 25Mose sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn.
Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.