Native Bible

Exodus 13:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa.

Exodus 13:6 in English

Exodus 13:6 · Berean Standard Bible

For seven days you are to eat unleavened bread, and on the seventh day there shall be a feast to the LORD.

Context

4Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. 5Ní ìgbà tí Olúwa mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. 6Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa. 7Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín. 8Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.