Native Bible

Exodus 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ìgbà tí Olúwa mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.

Exodus 13:5 in English

Exodus 13:5 · Berean Standard Bible

And when the LORD brings you into the land of the Canaanites, Hittites, Amorites, Hivites, and Jebusites—the land He swore to your fathers that He would give you, a land flowing with milk and honey—you shall keep this service in this month.

Context

3Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú. 4Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti. 5Ní ìgbà tí Olúwa mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí. 6Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa. 7Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.