Eksodu 12:36
Exodus 12:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojúrere àwọn ará Ejibiti wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Ejibiti.
Exodus 12:36 in English
Exodus 12:36 · Berean Standard Bible
And the LORD gave the people such favor in the sight of the Egyptians that they granted their request. In this way they plundered the Egyptians.
Context
34Àwọn ènìyàn náà sì mú ìyẹ̀fun púpọ̀ kí wọn tó fi ìwúkàrà sí i, wọ́n gbe le èjìká wọn nínú ọpọ́n tí wọ́n ti fi aṣọ dì. 35Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn. Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ ará Ejibiti fún ohun èlò fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ pẹ̀lú. 36Olúwa ti mú kí àwọn ènìyàn yìí rí ojúrere àwọn ará Ejibiti wọ́n sì fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún, wọ́n sì ko ẹrù àwọn ará Ejibiti. 37Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé. 38Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ni ó bá wọ́n lọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran ọ̀sìn, agbo àgùntàn àti agbo màlúù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.