Native Bible

Exodus 12:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; àti ní ọjọ́ keje àpéjọ mímọ́ mìíràn yóò wà fún yín. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, bí kò ṣe oúnjẹ tí olúkúlùkù yóò jẹ; kìkì èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe.

Exodus 12:16 in English

Exodus 12:16 · Berean Standard Bible

On the first day you are to hold a sacred assembly, and another on the seventh day. You must not do any work on those days, except to prepare the meals—that is all you may do.

Context

14“Ọjọ́ òní ni yóò sì máa ṣe ọjọ́ ìrántí fún yín, ẹ́yin yóò sì máa láàrín àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe ní àjọ fún Olúwa; ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. 15Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Israẹli. 16Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; àti ní ọjọ́ keje àpéjọ mímọ́ mìíràn yóò wà fún yín. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, bí kò ṣe oúnjẹ tí olúkúlùkù yóò jẹ; kìkì èyí ni gbogbo ohun tí ẹ̀yin lè ṣe. 17“Ẹ ó sì kíyèsí àjọ àìwúkàrà, nítorí ní ọjọ́ náà gan an ni mo mú ogun yín jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Nítorí náà ni kí ẹ máa kíyèsi ọjọ́ náà ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. 18Àkàrà ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún oṣù àkọ́kọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.