Eksodu 11:8
Exodus 11:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao.
Exodus 11:8 in English
Exodus 11:8 · Berean Standard Bible
And all these officials of yours will come and bow before me, saying, ‘Go, you and all the people who follow you!’ After that, I will depart.” And hot with anger, Moses left Pharaoh’s presence.
Context
6Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Irú ohun búburú tí kò ṣẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni ṣẹlẹ̀ mọ́. 7Ṣùgbọ́n láàrín àwọn ará Israẹli ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn.’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Ejibiti àti Israẹli. 8Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao. 9Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Farao yóò kọ̀ láti fetísílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Ejibiti.” 10Mose àti Aaroni ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Farao, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Israẹli jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.