Eksodu 10:9
Exodus 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe àjọ fún Olúwa.”
Exodus 10:9 in English
Exodus 10:9 · Berean Standard Bible
“We will go with our young and old,” Moses replied. “We will go with our sons and daughters, and with our flocks and herds, for we must hold a feast to the LORD.”
Context
7Àwọn ìjòyè Farao sọ fún un, “Yóò ti pẹ́ to tí ọkùnrin yìí yóò máa jẹ́ ìkẹ́kùn fún wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí síbẹ̀ pé, ilẹ̀ Ejibiti ti parun tán?” 8Nígbà náà ni a mú Aaroni àti Mose padà wá sí iwájú Farao ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.” 9Mose dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe àjọ fún Olúwa.” 10Farao sì wí pé, “Mo fi Olúwa búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín. 11Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yin ń béèrè fún.” Wọ́n sì lé Mose àti Aaroni kúrò ní iwájú Farao.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.