Eksodu 1:8
Exodus 1:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti.
Exodus 1:8 in English
Exodus 1:8 · Berean Standard Bible
Then a new king, who did not know Joseph, came to power in Egypt.
Context
6Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú, 7ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ń bí sí i, wọ́n ń pọ̀ sí i gidigidi, wọ́n kò sì ní òǹkà tí ó fi jẹ́ pé wọ́n kún ilẹ̀ náà. 8Nígbà náà ni ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 9Ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, “Ẹ wò ó, àwọn ará Israẹli ti pọ̀ ní iye àti agbára jù fún wa. 10Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí láti dá wọn lẹ́kun, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ogun bá sì bẹ́ sílẹ̀, wọn yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ọ̀tá wa, wọn yóò sì da ojú ìjà kọ wá, wọn yóò sì sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ yìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.