Native Bible

Esther 9:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.

Esther 9:19 in English

Esther 9:19 · Berean Standard Bible

This is why the rural Jews, who live in the villages, observe the fourteenth day of the month of Adar as a day of joy and feasting. It is a holiday for sending gifts to one another.

Context

17Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. 18Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. 19Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn. 20Mordekai ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ahaswerusi, tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré, 21láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù Addari ní ọdọọdún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.