Esteri 5:7
Esther 5:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Esteri sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí.
Esther 5:7 in English
Esther 5:7 · Berean Standard Bible
Esther replied, “This is my petition and my request:
Context
5Ọba sì wí pé, “ẹ mú Hamani wá kíákíá, nítorí kí a lè ṣe ohun tí Esteri béèrè fún un.”
Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti Hamani lọ sí ibi àsè tí Esteri ti pèsè. 6Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Esteri, “Báyìí pé: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọba mi, a ó fi fún ọ.” 7Esteri sì dáhùn, “Ẹ̀bẹ̀ mi àti ìbéèrè mi ni èyí. 8Bí ọba bá fi ojúrere rẹ̀ fún mi, tí ó bá sì tẹ́ ọba lọ́rùn láti gba ẹ̀bẹ̀ mi àti láti mú ìbéèrè mi ṣẹ, jẹ́ kí ọba àti Hamani wá ní ọ̀la sí ibi àsè tí èmi yóò pèsè fún wọn. Nígbà náà ni èmi yóò dáhùn ìbéèrè ọba.” 9Hamani jáde lọ ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí Mordekai ní ẹnu-ọ̀nà ọba, ó wòye pé kò dìde tàbí kí ó bẹ̀rù ní iwájú òun, inú bí i gidigidi sí Mordekai.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.