Native Bible

Esther 4:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Susa jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi. Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin. Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé.”

Esther 4:16 in English

Esther 4:16 · Berean Standard Bible

“Go and assemble all the Jews who can be found in Susa, and fast for me. Do not eat or drink for three days, night or day, and I and my maidens will fast as you do. After that, I will go to the king, even though it is against the law. And if I perish, I perish!*”

Context

14Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílé baba à rẹ yóò ṣègbé. Ta ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?” 15Nígbà náà ni Esteri rán iṣẹ́ yìí sí Mordekai: 16“Lọ, kí o kó gbogbo àwọn Júù tí ó wà ní Susa jọ, kí ẹ sì gbààwẹ̀ fún mi. Ẹ má ṣe jẹun tàbí omi fún ọjọ́ mẹ́ta, ní òru àti ní ọ̀sán. Èmi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi náà yóò gbààwẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti ṣe. Nígbà tí ẹ bá ṣe èyí, èmi yóò tọ ọba lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lòdì sí òfin. Bí mo bá sì ṣègbé, mo ṣègbé.” 17Bẹ́ẹ̀ ni Mordekai lọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí Esteri pàṣẹ fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.