Native Bible

Esther 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”

Esther 4:11 in English

Esther 4:11 · Berean Standard Bible

“All the royal officials and the people of the king’s provinces know that one law applies to every man or woman who approaches the king in the inner court without being summoned—that he be put to death. Only if the king extends the gold scepter may that person live. But I have not been summoned to appear before the king for the past thirty days.”

Context

9Hataki padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Esteri ohun tí Mordekai sọ. 10Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai, 11“Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.” 12Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai, 13nígbà náà ni Mordekai sọ kí a dá Esteri lóhùn pé, “Má ṣe rò nínú ara rẹ pé nítorí pé ìwọ wà ní ilé ọba ìwọ nìkan là láàrín gbogbo àwọn Júù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.