Esteri 4:10
Esther 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai,
Esther 4:10 in English
Esther 4:10 · Berean Standard Bible
Then Esther spoke to Hathach and instructed him to tell Mordecai,
Context
8Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun wọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Susa, láti fihan Esteri kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún un, ó sì sọ fún un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ síwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀. 9Hataki padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Esteri ohun tí Mordekai sọ. 10Nígbà náà ni Esteri pàṣẹ fún Hataki pé kí ó sọ fún Mordekai, 11“Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pé a ránṣẹ́ pè é (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá wúrà rẹ̀ sí i kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.” 12Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Esteri fún Mordekai,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.