Esteri 3:7
Esther 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari.
Esther 3:7 in English
Esther 3:7 · Berean Standard Bible
In the twelfth year of King Xerxes, in the first month, the month of Nisan,* the Pur (that is, the lot) was cast before Haman to determine a day and month. And the lot fell on the twelfth month, the month of Adar.*
Context
5Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. 6Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi. 7Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari. 8Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. 9Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.