Native Bible

Esther 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báyìí ni yóò ṣe lọ síwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba.

Esther 2:13 in English

Esther 2:13 · Berean Standard Bible

When the young woman would go to the king, she was given whatever she requested to take with her from the harem to the king’s palace.

Context

11Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i. 12Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú. 13Báyìí ni yóò ṣe lọ síwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba. 14Ní alẹ́ ni yóò lọ síbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyàfi tí inú ọba bá dùn sí i, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin. 15Nígbà tí ó kan Esteri (ọmọbìnrin tí Mordekai gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Abihaili) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò béèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Esteri sì rí ojúrere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.