Esteri 2:12
Esther 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú.
Esther 2:12 in English
Esther 2:12 · Berean Standard Bible
In the twelve months before her turn to go to King Xerxes, the harem regulation required each young woman to receive beauty treatments with oil of myrrh for six months, and then with perfumes and cosmetics for another six months.
Context
10Esteri kò tí ì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Mordekai ti pàṣẹ fún un pé kí ó má ṣe sọ ọ́. 11Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i. 12Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú. 13Báyìí ni yóò ṣe lọ síwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba. 14Ní alẹ́ ni yóò lọ síbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyàfi tí inú ọba bá dùn sí i, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.