Efesu 5:21
Ephesians 5:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Ephesians 5:21 in English
Ephesians 5:21 · Berean Standard Bible
Submit to one another out of reverence for Christ.*
Context
19Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá. 21Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 22Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. 23Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.