Efesu 5:2
Ephesians 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.
Ephesians 5:2 in English
Ephesians 5:2 · Berean Standard Bible
and walk in love, just as Christ loved us * and gave Himself up for us as a fragrant sacrificial offering to God.
Context
1Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, 2ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn. 3Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́. 4Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.