Native Bible

Ecclesiastes 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Máa wọ aṣọ funfun nígbàkígbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo.

Ecclesiastes 9:8 in English

Ecclesiastes 9:8 · Berean Standard Bible

Let your garments always be white, and never spare the oil for your head.

Context

6Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn, àti ìlara wọn ti parẹ́: láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. 7Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe. 8Máa wọ aṣọ funfun nígbàkígbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. 9Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.