Oniwaasu 9:12
Ecclesiastes 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé, gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.
Ecclesiastes 9:12 in English
Ecclesiastes 9:12 · Berean Standard Bible
For surely no man knows his time: Like fish caught in a cruel net or birds trapped in a snare, so men are ensnared in an evil time that suddenly falls upon them.
Context
10Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ. 11Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn.
Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára
tàbí ogun fún alágbára,
bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n
tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye
tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;
ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. 12Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé,
gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú
tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi
tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀. 13Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn. 14Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.