Oniwaasu 7:3
Ecclesiastes 7:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.
Ecclesiastes 7:3 in English
Ecclesiastes 7:3 · Berean Standard Bible
Sorrow is better than laughter, for a sad countenance is good for the heart.
Context
1Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ,
ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ. 2Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀
ju ibi àsè,
nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn;
kí alààyè ní èyí ní ọkàn. 3Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ,
ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú,
ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le. 4Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá. 5Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,
ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.