Oniwaasu 7:22
Ecclesiastes 7:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.
Ecclesiastes 7:22 in English
Ecclesiastes 7:22 · Berean Standard Bible
For you know in your heart that many times you yourself have cursed others.
Context
20Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé
tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá. 21Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ
bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ. 22Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ
pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn. 23Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,
“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”;
ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ. 24Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,
ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀
ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.