Oniwaasu 7:11
Ecclesiastes 7:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
Ecclesiastes 7:11 in English
Ecclesiastes 7:11 · Berean Standard Bible
Wisdom, like an inheritance, is good, and it benefits those who see the sun.
Context
9Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ
nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé. 10Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”
Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. 11Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára
ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní. 12Ọgbọ́n jẹ́ ààbò
gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò
ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí
pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní. 13Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:
“Ta ni ó le è to
ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.