Native Bible

Ecclesiastes 6:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí.

Ecclesiastes 6:7 in English

Ecclesiastes 6:7 · Berean Standard Bible

All a man’s labor is for his mouth, yet his appetite is never satisfied.*

Context

5Bí ó ti jẹ́ wí pé kò rí oòrùn tàbí mọ ohunkóhun, ó ní ọ̀pọ̀ ìsinmi ju ti ọkùnrin náà lọ. 6Kódà, bí ó wà láààyè fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún méjì yípo ṣùgbọ́n tí ó kùnà láti gbádùn ohun ìní rẹ̀. Kì í ṣe ibìkan ni gbogbo wọn ń lọ? 7Gbogbo wàhálà tí ènìyàn ń ṣe nítorí àtijẹ ni síbẹ̀ ikùn rẹ̀ kò yó rí. 8Kí ni àǹfààní tí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní lórí aṣiwèrè? Kí ni èrè tálákà ènìyàn nípa mímọ bí yóò ṣe hùwà níwájú àwọn tókù? 9Ohun tí ojú rí sàn ju ìfẹnuwákiri lọ. Asán ni eléyìí pẹ̀lú ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.