Oniwaasu 6:1
Ecclesiastes 6:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn.
Ecclesiastes 6:1 in English
Ecclesiastes 6:1 · Berean Standard Bible
There is another evil I have seen under the sun, and it weighs heavily upon mankind:
Context
1Mo ti rí ibi mìíràn lábẹ́ oòrùn. 2Ọlọ́run fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀, ọlá àti ọlà kí ó má ba à ṣe aláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kò fún un ní àǹfààní láti gbádùn wọn, dípò èyí, àlejò ni ó ń gbádùn wọn. Asán ni èyí, ààrùn búburú gbá à ni. 3Ọkùnrin kan le è ní ọgọ́rùn-ún ọmọ kí ó sì wà láààyè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, síbẹ̀ kò sí bí ó ti le wà láààyè pẹ́ tó, bí kò bá le è gbádùn ohun ìní rẹ̀ kí ó sì gba ìsìnkú tí ó tọ́, mo sọ wí pé ọlẹ̀ ọmọ tí a sin sàn jù ú lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.