Native Bible

Ecclesiastes 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀.

Ecclesiastes 4:14 in English

Ecclesiastes 4:14 · Berean Standard Bible

For the youth has come from the prison to the kingship, though he was born poor in his own kingdom.

Context

12Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já. 13Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn. 14Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. 15Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. 16Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.