Oniwaasu 2:9
Ecclesiastes 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.
Ecclesiastes 2:9 in English
Ecclesiastes 2:9 · Berean Standard Bible
So I became great and surpassed all in Jerusalem who had preceded me; and my wisdom remained with me.
Context
7Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. 8Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. 9Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. 10Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.
N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.
Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,
èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. 11Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣe
àti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:
gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹni
gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;
ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.