Oniwaasu 12:1
Ecclesiastes 12:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ ní ọjọ́ èwe rẹ, nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé, “Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,”
Ecclesiastes 12:1 in English
Ecclesiastes 12:1 · Berean Standard Bible
Remember your Creator in the days of your youth, before the days of adversity come and the years approach of which you will say, “I find no pleasure in them,”
Context
1Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ
ní ọjọ́ èwe rẹ,
nígbà tí ọjọ́ ibi kò tí ì dé
àti tí ọdún kò tí ì ní súnmọ́ etílé, nígbà tí ìwọ yóò wí pé,
“Èmi kò ní ìdùnnú nínú wọn,” 2kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀
àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn,
àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò; 3nígbà tí olùṣọ́ ilé yóò wárìrì
tí àwọn ọkùnrin alágbára yóò tẹríba,
nígbà tí àwọn tí ó ń lọ dákẹ́ nítorí pé wọn kò pọ̀,
tí àwọn tí ń wo òde láti ojú fèrèsé yóò ṣókùnkùn;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.