Oniwaasu 10:18
Ecclesiastes 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.
Ecclesiastes 10:18 in English
Ecclesiastes 10:18 · Berean Standard Bible
Through laziness the roof caves in, and in the hands of the idle, the house leaks.
Context
16Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀. 17Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọlọ́lá,
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,
fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara. 18Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì
bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó. 19Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,
wáìnì a máa mú ayé dùn,
ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo. 20Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,
tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,
nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ
ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.